Ibà
Àdàkọ:Infobox medical condition (new)
'''Ibà''' jẹ aisan ti eniyan tabi eranko miran le ko nigba ti efon ba je won.[1][2][3] Awon apeere ti a le fi mo wipe eniyan ni aisan iba ni otutu, aare ara, eebi ati ori fifo. [4][5] Lopo igba, aisan le mu ki oju eniyan o pon, ki giri o muni, ki eniyan o daku tabi iku ojiji.[4] Awon apeere ti a ti menuba loke yi yoo bere laarin ojo mewa si ojo meedogun leyin ti efon ba ti jeni. [3] Bi a ko ba setoju aisan iba, o see se ki o tun pada muni laimoye igba leyin osu die. [3] Amo, bi o ba tun seyo lara eni ti o ti gba itoju ti o peye tele, ko ni fi bee lagbara pupo.[4] Bi efon ko ba je eni ti o ti ni aisan iba ri mo, aisan iba ko ni gbe irufe eni bee sanle mo.[4]
Ibà je àmì aìsàn ti o wopo, ara ònà ti a fi n se wadi re ni ki a lo òsùnwàn ìgbóná (ti awon oyinbo n pe ni "thermometer").
Awọn kokoro aifojuri alabala ẹyọkan ti ẹgbẹ Plasmodium ni o ma n fa Iba eniyan.[6] Aisan iba ma n tan kaakiri nipasẹ awọn ẹfọn Anopheles ti o ni arun nigbati won ba ge eniyan je.[6][7] Jijẹ ẹfọn ma n da awọn kokoro parasite lati itọ ẹfọn papo mo ẹjẹ eniyan.[6] Awọn kokoro parasite yii ma n lọ si inu edo eniyan, nibiti wọn ti maa dagba ti won a si maa bimo lati po si.[8] Ẹya marun ti Plasmodium lo le fa akoran ati titan kaakiri aisan iba lara eniyan.[8] P. falciparum ni o ma n fa iku lopolopo ju, sugbon P. vivax, P. ovale, ati P. malariae ni won ma n fa iru ibà kan to lo wooro diẹ.[8][6] Ẹya P. Knowlesi ṣọwọn nibi fifa aisan laarin eniyan.[6] Ayẹwo iba ma n waye nipasẹ iwadi re ninu ẹjẹ eniyan, tabi pẹlu awọn idanwo iwadii ti o da lori antigen.[8] Idagbasoke ti ba awọn ọna ti o nilo iṣesi ẹwọn polymerase lati ṣe awari DNA ti parasite ti aisan iba, ṣugbọn wọn ko tii je lilo ni awọn agbegbe ti ibà ti wọpọ, nitori owongogo ati idiju wọn.[9]
Ewu aisan le dinku nipa didi ẹfọn lọwọ bibuje nipasẹ lilo awon àwọ̀n ẹ̀fọn ati awọn ogun apakokoro tabi pẹlu awọn igbese iṣakoso ẹfọn gẹgẹbi fifọn ogun ipakokoro ati fifa omi adagun kuro.[10] Orisirisi awọn oogun lo wa lati dena iba fun awọn aririn ajo ni awọn agbegbe ti aisan naa ti wọpọ.[11] Lilo apapọ oogun sulfadoxine/pyrimethamine leekọọkan ni awọn onimọ fe ki a lo fun ọmọ ikoko ati fun aboyun ti oyun inu re ti le loṣu mẹta ni awọn agbegbe ti iba ti wọpọ.[11] Ni ọdun 2020, ajẹsara kan han lati din eewu iba ku ni iwọn 40% laarin awọn ọmọde ni Afirika.[12][13] Iwadi iṣaaju nipa ajesara miiran safihan ikapa ajesara naa ni iwọn 77%.[14] Awọn igbiyanju lati ṣe agbekalẹ awọn oogun ajesara to munadoko ti nlọ lọwọ.[13] Itọju ti o ni ibamu si iba jẹ apapọ awọn oogun ajẹsara ti o ni artemisinin.[15][16][10][11] Oogun keji le jẹ boya mefloquine, lumefantrine, tabi sulfadoxine/pyrimethamine.[17] Quinine pẹlu doxycycline ṣee lo papọ ti artemisinin ko ba si.[17] Ni awọn agbegbe ti aisan na ti wọpọ, aridaju iba se pataki ṣaaju ki itọju to bẹrẹ nitori aisise oogun .[11] Aisise oogun laarin awọn parasite ti se okufa idagbasoke ọpọlọpọ awọn oogun ajẹsara; fun apẹẹrẹ, P. falciparum ti o soro fun chloroquine lati pa ti tàn kaakiri ọpọlọpọ awọn agbegbe ti ibà ti wọpọ, bẹẹ si ni idiwọ si oogun artemisinin ti di iṣoro ni awọn agbegbe kookan ni Guusu ila oorun Asia.[11]
Wo eléyí náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]• Ako ibà
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Vector-borne diseases". www.who.int (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-24.
- ↑ "The male mosquito contribution towards malaria transmission: Mating influences the Anopheles female midgut transcriptome and increases female susceptibility to human malaria parasites". PLOS Pathogens 15 (11): e1008063. November 2019. doi:10.1371/journal.ppat.1008063. PMC 6837289. PMID 31697788. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=6837289.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedWHO2014
- ↑ 4.0 4.1 4.2 4.3 "Emergency department management of mosquito-borne illness: malaria, dengue, and West Nile virus". Emergency Medicine Practice 16 (5): 1–23; quiz 23–4. May 2014. PMID 25207355. http://www.ebmedicine.net/topics.php?paction=showTopic&topic_id=405.
- ↑ "Malaria: An Update". Indian Journal of Pediatrics 84 (7): 521–528. July 2017. doi:10.1007/s12098-017-2332-2. PMID 28357581.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 6.3 6.4 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedWHO20142
- ↑ "Malaria". JAMA 327 (6): 597. February 2022. doi:10.1001/jama.2021.21468. PMID 35133414.
- ↑ 8.0 8.1 8.2 8.3 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedCara20142
- ↑ "Malaria: an update for physicians". Infectious Disease Clinics of North America 26 (2): 243–259. June 2012. doi:10.1016/j.idc.2012.03.010. PMID 22632637.
- ↑ 10.0 10.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedCara20143
- ↑ 11.0 11.1 11.2 11.3 11.4 "Malaria Fact sheet N°94". WHO. March 2014. Archived from the original on 3 September 2014. Retrieved 28 August 2014.
- ↑ "Fact sheet about Malaria". www.who.int (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 May 2020.
- ↑ 13.0 13.1 "Malaria vaccine: WHO position paper-January 2016". Relevé Épidémiologique Hebdomadaire 91 (4): 33–51. January 2016. PMID 26829826. https://www.who.int/wer/2016/wer9104.pdf?ua=1.
- ↑ "Efficacy of a low-dose candidate malaria vaccine, R21 in adjuvant Matrix-M, with seasonal administration to children in Burkina Faso: a randomised controlled trial". Lancet 397 (10287): 1809–1818. May 2021. doi:10.1016/S0140-6736(21)00943-0. PMC 8121760. PMID 33964223. SSRN 3830681. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=8121760.
- ↑ "Cysteine proteases: Battling pathogenic parasitic protozoans with omnipresent enzymes". Microbiological Research 249: 126784. August 2021. doi:10.1016/j.micres.2021.126784. PMID 33989978.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedwho2022
- ↑ 17.0 17.1 Guidelines for the treatment of malaria (2nd ed.). Geneva: World Health Organization. 2010. p. ix. ISBN 978-92-4-154792-5.
- "CareCentral Urgent Care 2020">"When to seek treatment for a fever". CareCentral Urgent Care. 2020-01-03. Retrieved 2022-02-18.
- Health direct 2021">"Paracetamol". healthdirect. 2021-07-18. Retrieved 2022-02-18.
- "Fever: Symptoms, Causes, Care & Treatment". Cleveland Clinic. Retrieved 2022-02-18.