[go: up one dir, main page]

Jump to content

The good Muslim

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
The Good Muslim
Fáìlì:The Good Muslim book cover.jpg
The cover image of The Good Muslim (HarperCollins edition)
Olùkọ̀wéTahmima Anam
CountryUnited Kingdom
LanguageEnglish
GenreHistorical novel, Romance novel, Domestic fiction
PublisherHarperCollins
Publication date
August 2, 2011
Media typePrint (Hardcover, Paperback)
Pages304
ISBNÀdàkọ:ISBNT
OCLC701243911
Preceded byA Golden Age 
Followed byThe Bones of Grace 

The Good Muslim jẹ́ ìwé ìtàn àròsọ láti ọwọ́ Tahmima Anam.Ìwé ìtàn àròsọ yìí jẹ́ èyí tó tẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ ìwé ìtàn àròsọ rẹ̀ tó kọ́kọ́ kọ, tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní A Golden Age tí ó sì lo ọdún kan, láti ọdún 1984 sí 1985, ohun tó jẹ́ àkóónú rẹ̀ náà ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ogun ìjìjàgbara Bangladesh ní ọdún 1971,ìtàn tó sọ nípa ìgbàgbọ́ àti àwọn ẹbí tí ogun jà ni. Àwọn ẹbí tó sì kópa nínú ogun ìjìjàgbara náà báyìí ń kojú ìpènijà àlàáfíà nílé àti lóko báyìí.

Ìsọníṣókí àhunpọ̀ ìtàn náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn olú-ẹ̀dá-ìtàn inú ìwé ìtàn àròsọ náà ni Maya and Sohail. Nígbà tí A Golden Age ń sọ ìtàn wọn ní àsìkò kí ogun ìjìjàgbara Bangladesh tó ṣẹlẹ̀ àti ìgbà tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́, ni The Good Muslim ń sọ ìtàn wọn lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí ogun náà ti ṣẹlẹ̀.

Ní ọdún 1984, Maya padà sílé lẹ́yìn bí ọdún mẹ́wàá tó ti kúrò nílé, tí ó sì ri pé àbúrò òun ti yí padà pátápátá. Ó sì ni ìtara sí kí ǹkan yí padà, ṣùgbọ́n ó ri pé Sohail ti fi ìsinmi síbi ẹ̀sìn Ìsìlámù látàrí a ti tẹ́ ìfẹ́ inú rẹ̀, tí ó sì ti di olórí tó lọ́yàyà nínú ìjọ náà lábẹ́ ìṣèjọba Ọ̀gágun Hussain Muhammad Ershad tí ó jẹ́ Ààrẹ àti Ológun tí ó gbé Ìsìlámù lárugẹ nípa àìfi igbá kan bọ́ ọkàn nínú. Ìyàtọ̀ èrò tó wà nínú àwọn méjèèjì yìí ti mú ìyapa bá èròǹgbà àwọn méjèèjì. Ìyàtọ̀ yìí gan wá á ni kókó ìrúkèrúdò nínú ìwé The Good Muslim. Àwọn méjèèjì ti ya àtẹ àwòrán èyí tó yàtọ̀ gédéńgbé sí ara fún Ìlọsíwájú àwọn ìtàn tó ti wọ́. Maya jẹ́ oníṣègùn abúlé tó lawọ́,tí ó sì máa ń ran àwọn obìnrin tó bá farapa níbi ogun. Ó máa ń sẹ́yún fún àwọn obìnrin tí wọ́n bá fi ipá bá lópọ̀ kí oyún náà ma bà á dè wọ́n mọ́ ojú kan. Nítorí èyí, orísìírísìí ohun ìyanu ni ó máa ń rí níbi gbogbo ní gbogbo ìgbà. Bí Sohail ṣe wá jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí dáradára tó, èyí yàtọ̀ gédéńgbé sí ti àbúrò rẹ̀, nítorí ìlànà ìṣẹ̀ṣìn ti Tablig Jamaat ni ó ń tẹ̀lé, èyí tí ó sì pa pé kí a máa fi orin ṣe ìdùnnú tàbí kó ọ̀rẹ́ tàbí lo ayé pẹ̀lú àwọn ìwúlò rẹ̀ lásán, Sohail fẹ́ rán ọmọ rẹ̀ lọ sí ilé kéwú látàrí èyí ìrúkèrúdò wáyé, tí ó sì mú opin dé góńgó.[1]

Àwọn àgbéyẹ̀wò tó wà nílẹ̀ The Good Muslim sáábà dára. Valerie Miner titi ìgbà Los Angeles Times sọ pé "The Good Muslim ṣàlàyé lẹ́kùn-ùn rẹ́rẹ́,ó fa ìtàn mu àti àti bí àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tó le ní sísẹ̀ǹtẹ̀lé... èyí tó jẹ́ ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ewu tí a kò lérò pé ó lè ṣẹlẹ̀ wà nínú ìtara tàbí agbára ẹ̀sìn, rògbòdìyàn ètò òṣèlú, bákan náà fún kíkùndùn sí ìdánwò fún ìdóòla àti ìdáríjì."[2] Ní yíyin ìwé, The Guardian sọ pé "Ó lágbára ó sì tún jẹ́ onífẹ̀ẹ́ tó lágbára, The Good Muslim ju pé ó mú ìlérí ayẹyẹ àkọ́kọ́ tí i ṣe, A Golden Age".[3] Nínú àgbéyẹ̀wò Publishers Weekly ó sọ pé, tí a bá ń yin ìwé yìí pẹ̀lú ọ̀nà tí a fi rọ wo ìwé A

A, Ó dúró ṣinṣin ó sì tún rẹwà ní kíkọedìwé ìtàn àròsọ yìíhe nínúukí a sọ nípa ládojúdé ìtàn,ètò òṣèlú àti àwùjọ, Anam ní bí ó ṣe mú ìtàn àti àṣà papọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà. rnal Transnational Literature published from the Flinders University,

Wọn ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún ẹ̀bùn ní DSC ní lítíresọ̀ South Asian.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]