[go: up one dir, main page]

Jump to content

Ada ọmọ daddy

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ada ọmọ daddy
Adarí
  • Akay Mason
  • Adebayo Tijani
Olùgbékalẹ̀Mercy Aigbe
Òǹkọ̀wéYakubu Olawale
Àwọn òṣèré
OrinAdam Songbird
Ìyàwòrán sinimáBarnabas Emordi
OlóòtúAdio Solanke
OlùpínCinemax distribution
Déètì àgbéjáde15 December 2023
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish

Ada, Ọmọ Daddy jẹ́ eré àgbéléwò tí wọ́n gbé jáde ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2023,tí ó ń pa ni lẹ́rìn-ín tí Yakubu Olawale sì kọ. Mercy Aigbe[1], Akay Mason àti Adebayo Tijani ni wọ́n gbé e jáde tí wọ́n sì darí rẹ̀. Fíìmù náà dá lórí , ìtànjẹ nípa òbí tí àṣírí sì tú ní ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó. Àwọn òṣèré Nollywood bíi Charles Okafor , Sola Sobowale, Mercy Aigbe, Chiwetalu Agu àti Uche Ndubuisi.[2][3]

Agbékalẹ̀ eré náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ada Omo Daddy sọ ìtàn Pero (Omowumi Dada) ,ẹni tí ó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó pẹ́lú Victor (Tayo Faniran). Ilé-ayé Pero yí padà ní ọ̀nà tí ó yani lẹ́nu nígbà tí Ifeanyi (Charles Okafor) dédé yọjú tí ó sì sọ wípé òun ni bàbá tí ó bí i,èyí tí ó dá wàhálà sílẹ̀ ní ilé Balogun tí ó tòòrò tẹ́lẹ̀ . Jíjáde tí Ifeanyi jáde lójijì yìí, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé kò kọbi ara tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ti yí padà báyìí ,tú àwọn àṣírí tí ó ti wà sẹ́yìn ,tí ó sì gbọ́dọ̀ ní ìyànjú kí Pero àti Victor tó ṣe ìgbéyàwó. [4]

  • Sola Sobowale bíi Mrs. Ireti Balogun
  • Mercy Aigbe bíi Motunrayo tó ti dàgbà
  • Omowumi Dada bíi Peresola Balogun
  • Tayo Faniran bíi Victor
  • Charles Okafor
  • Chiwetalu Agu bíi Uncle Ndubuisi
  • Uche Ndubuisi
  • Taiwo Adeyemi
  • Adeniyi Johnson bíi Ifeanyi (nígbà tó ṣì kéré)
  • Carol King bíi Mrs. Ekpeyong
  • Dele Odule bíi Chief Balogun
  • Tomi Ojo bíi Fara
  • Nkechi Blessing bíi Ndidi
  • Unusual Phyna bíi Ìrètí (ní ọmọdé)
  • Miriam Peters bíi Ezinne

Ada Omo Daddy wà lára fíìmù tí Premium Times fi sí ara fíìmù mẹ́wàá àkọ́kọ́ fún àsìkò ọdún ní ọdún 2023.[5]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Nigeria, Guardian (2023-09-02). "Mercy Aigbe: On why ' Ada Omo Daddy' is the movie to anticipate". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2024-02-19. Retrieved 2024-02-18. 
  2. "Movie Title: Ada Omo Daddy". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2024-02-17. Retrieved 2024-02-18. 
  3. Stephen, Onu (2023-12-26). "'Ada Omo Daddy': 'Wedding Party' copy that falls short in several ways". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-18. 
  4. Oloruntoyin, Faith (2023-11-27). "Love becomes chaotic in Mercy Aigbe's star-packed 'Ada Omo Daddy' trailer". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-18. 
  5. Olusola, Elijah (2023-12-25). "Ada Omo Daddy, Osato, Nine other movies to watch this season". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-19.